ÌTÀN ÌGBÉSÍ-AYÉ ÀWỌN OLÓRIN YORÙBÁ (APÁ KEJÌ)

K1 De Ultimate (Wasiu Omogbolahan Olasunkanmi Adewale Ayinde Marshal)

A bí Oluwasunkammi Ayinde marshal ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹta ọdún 1957. Ó jẹ́ gbajúmọ̀ olórin Fújì lábẹ́ ẹ iṣẹ́ ẹ Olùdásílẹ̀ Fújì nì Ayinde Barrister tí a mọ̀ sí Talazo Fuji tó la gbogbo ẹ̀yà, ọjọ́-orí àti ìran.

Ọba orin Fújì ; Oluwasunkammi Ayinde Marshal, K1 De Ultimate ṣàwárí ìtara rẹ̀ fún iṣẹ́ orin láti ọmọ ọdún mẹ́jọ àwọn rẹ̀ kò faramọ́ ṣùgbọ́n ó tẹ̀síwájú nínu ìtara rẹ̀, ní ọmọ ọdún márùn-úndílógún, Ó jáwé olúborí nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdíje orin ní ẹsẹ̀-kùkú. Ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ orin Ayinde Barrister, The Supreme Fuji Commanders láti 1975 sí 1978 lẹ́hìn tí ó ti sìn bíi Akó-ohun-èlò orin. Ó gba orúkọ Ayinde sínú orúkọ rẹ̀ nípa gbígba àyè àti ìwúre lọ́wọ́ ọ ọ̀ga rẹ̀ Ayinde Barrister. Ó ṣe àwo rẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó pè ní Iba pẹ̀lú orin ” Abode Mecca” ní 1980,àwo rẹ̀ tí ó tayọ jù ní Talazo’84 ní 1984 ó gba oríṣiríṣi oyè àti orísirísi àmì-ẹ̀yẹ orin.

K1 De Ultimate bẹ̀rẹ̀ ìmọ̀lú lọ àgbáyé láàárín North-America àti Europe ní 1986 ó sì seré ní Hammersmith Town Hall ní 1987. New York City tẹ̀lé e, United State pẹ̀lú gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ Talazo ní oṣù kẹsàn-án,1990, London Yuppie 1&2, Night 1991/92, European Tour 1995.

Ó tẹ̀síwájú nínu ìmọ̀lúlọ lọ́dọọdún, ní 1995 ó seré àkọ́kọ́ irú ẹ̀ ní WOMAD. òun ni olórin àkọ́kọ́ tó seré ní Troxy, WOMEX àti SOB. A fi àmì-ẹ̀yẹ àti oyè dá a lọ́lá. Wọn fi jẹ oyè àti àwọn àwọn àmì-ẹ̀yẹ bíi: Badabarawu of Ogijo in 1985

Ekerin Amuludun of Ibadanland in 1986
Golden Mercury of Africa Title in 1986,
Honoris Causa of Music at Saint John University Bakersfield California USA in 1989.
Crown as King of Fuji, (Oluaye Fuji Music) at NTA Ibadan in 1993.
The Oluomo of Lagos by King Adeyinka Oyekan of Lagos in 1999 [1]
On Monday, January 13, 2020, he was installed by the Alaafin of Oyo, Oba Lamidi Adeyemi as the first Mayegun of Yorubaland.[5]Merit Award title M.O.N member of other Niger by president Muhammad Buhari on 11 October 2022,this page Arrange and list by Gani Olawale Sodiq Tgaine
Wasiu Ayinde Marshal Officially Crowned as Olori Omooba of Akile ijebuland on 26 September 2023 by King Sikiru Adetona Awujale of Ijebu land, owner of Mayegun Resort Ijebu Ode K1 de ultimate Grant Another title as Otunba Fidipote mole of Fidipote dynasty the same September 2023,( TGAINE INTERNATIONAL 2023 )
Àwọn àwo orin tí ó ti kọ ní wọ̀nyí:

1980: Iba (TGaine)
1981: Esi Oro (TGaine)
1982: Igbalaye (TGaine)
1984: Talazo System (TGaine)
1984: Talazo ’84 (TGaine)
1984: Ise L’Ogun Ise (TGaine)
1984: Ijo olomo (TGaine)
1985: Talazo Disco 85 (TGaine)
1985: Alhaji Chief Wasiu Ayinde Barrister and His Talazo Fuji Commanders Organisation Oloriki Metta / Ki De Se [p] Vinyl LP Leader Record / LRC (LP) 05 (TGaine)
1985: Elo-Sora (TGaine)
1985: Pomposity (TGaine)
1986: Ori (TGaine)
1986: Tiwa Dayo (TGaine)
1986: Erin Goke – Lecture (TGaine)
1986: Baby Je Kajo (TGaine)
1987: Talazo In London (TGaine)
1987: Aiyé (TGaine)
1987: Adieu Awolowo (TGaine)
1988: Sun – Splash (TGaine)
1988: Fuji Headline (TGaine)
1988: My Dear Mother (TGaine)
1989: Fuji Rapping–– (TGaine)
1989: Achievement (TGaines)
1990: Jo Fun Mi (Dance For Me) (TGaine)
1991: American Tips
1991: Fuji Collections (TGaine)
1993: The Ultimate (TGaine)
1995: Consolidation (TGaine)
1995: Reflection (TGaine)
1995: Talazo Fuji Party Music Compact Disk (TGaine)
1996: Legacy (TGaine)
1996: Faze 2 Global Tour ’96 (TGaine)
1997: History (Edited by TGaine)
1997: Berlin Compact Disk (TGaine)
1999: Fuji Fusion (Okofaji Carnival) (TGaine)
2000: New Era (TGaine)
2000: Faze 3 (TGaine)
2001: Message (TGaine)
2001: Statement (TGaine)
2001: New Lagos (TGaine)
2002: Gourd (TGaine)
2003: Big Deal (TGaine)
2006: Flavour (TGaine)
2011: Tribute To My Mentor (TGaine)
2012: Instinct (TGaine)
2012: Fuji Time (TGaine)
2017: 22 Dec Fuji Ep Let Music Flow (TGaine)
2020 Fuji The Sound Fuji Hip ( Gani Olawale Sodiq, tgaine)
2022 Timeless ( Gani Olawale Sodiq Tgaine)
Lára àwọn orin rẹ( tí Gani Olawale Sodiq, TGaine ṣe àkójọ rẹ ni)

1984: Talazo System

1984: Omo Akorede
1986: Golden Mercury
1989: Siliky
1990: American Tour Live
1991: Yuppie Night 1 n 2
1994: Consolidation live Ade Bendel
1995: Sabaka Night
1995: Oju Opon
1995: Fadaka Club
1995: London Hamburg Amsterdam Berlin 95
1997: London Hamburg Amsterdam Berlin Paris 97
1998: United Kingdom Live
1998: New York Chicago Atlanta Houston & Canada Tour Toronto Montreal live 1998
1999: New Era Live United Kingdom
1999: Afinni
2000: Canada live
2007: United Kingdom Ireland Tour Live
2007: The Truth Live
Àti àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré ní ìpínlẹ̀ Èkó àti USA ní ọdún 1990

1995 Womad Concert
1997 Benson & Hedges
1999 Benson & Hedges Loud in Lagos
2020 Fuji the Sound ep

Alamu Atatalo

Alamu Atatalo jẹ́ Olùdásílẹ̀ Sekere ọ̀kan nínú àṣà orin Yorùbá. Ó jẹ́ ọmọ mọ ìlú Ìbàdàn, ó jẹ́ gbajúmọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá ní ọdún 1950 àti ìbẹ̀rẹ̀ 1960 ní àárín 1960 òkìkí rẹ̀ kàn látàri ẹ̀sùn ìbàjẹ́ kan tí a fi kàn án, láti ọwọ́ àwọn Detractors, láti wẹ ara rẹ̀ mọ́, ó tiraka láì sàárẹ̀ fún bíi ọdún kan láti tún orúkọ rẹ̀ ṣẹ. Ó pàdà wá láti gba ipò rẹ̀ padà gẹ́gẹ́ bíi Ọba Sẹ̀kẹ̀rẹ̀ ní àárín 70’s nípa ṣíṣe àwọn àwo orin jáde,LP record,irú orin sekere ọ̀un àti Alhaji Danda Epo-Akara jẹ́ orin to gbajúmọ̀ ní ojú-agbo ní Ìbàdàn ṣáájú orin Ayinde Barrister.

 

Isaiah Kehinde Dairo MBE

A bí I.K Dairo sí ìlú ọ̀fà ní ìpínlẹ̀ kwara ní 1930. Ìdílé r wá láti ìjèbú-jèsà kí wọ́n tó lọ sí ìlú Ọ̀fà. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Christian Missionary Primary School ní Ọ̀fà. Ó fi ilé-ẹ̀kọ́ sílẹ̀ nítorí ètò ìṣúná ìdílé rẹ̀. Ó kúrò ní ìlú Ọ̀fà lọ sí ìlú ìjẹ̀bú-jẹ̀ṣà níbi tó ti yan iṣẹ́ ẹ gberungberun láàyò.

Nínu ìrìn-àjò rẹ̀,ó gbé ìlù tí bàba rẹ̀ bá a ṣe nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún méje. Nígbà tí ó ń gbé ní ìjèbú-jèsà, ó ti fẹ́ràn láti máa lùlù. Ó máa fi àwọn àkókò tí kò bá ní isé gbó orin juju.

Ìfẹ́ rẹ̀ fún orin juju dàgbà síi, ní ọdún 1942,o darapọ̀ mọ́ ègbẹ́ orin kan tí Taiwo Igese jẹ́ adarí láàárín ọdún díẹ̀ ẹgbẹ́ náà túká. Ní 1948, Ó lọ sí ìlú Ede, ìlú kan ní ìpínlẹ̀ Osun níbi tó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ èjìká ni sọ́ọ̀bù á sì máa kọrin ẹsẹ̀kùkú. Lọ́jọ́ kan, ọ̀gá rẹ̀ rìnrìn àjò, I.K Dairo pinu láti darapọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ láti lọ sí ibi ìnáwó kan láì mọ̀ pé ọ̀ga rẹ̀ yóò wà níbẹ̀ ṣùgbọ́n sí ìyàlẹ́nu ọ̀ga rẹ̀ nítorí èyí, ọ̀ga rẹ̀ yọ ọ́ ní isé.

I.K Dairo gbìyànjú láti sa owó jọ lẹ́hìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti lọ sí ìlú Ìbàdàn, níbi ti Daniel Ojoge olórin juju ti ń kọrin. Ó ní àǹfàní láti darapọ̀ mọ́ fún ìgbà díẹ̀ kí ó tó padà sí ìlú ìjẹ̀bú-jẹ̀ṣà, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tí ó ṣe pẹ̀lú ẹgbẹ́ Ojoge jẹ́ alẹ́.

Ní 1957, I.K Dairo dá ẹgbẹ́ The Morning Star Orchestra kalẹ̀ pẹ̀lú ọmọ ẹgbẹ́ mẹ́wà èyí tó mú ìrìn-àjò iṣẹ́ orin rẹ̀ yá kánkán.Ní 1960, nígbà ayẹyẹ òmìnira Nàìjíríà, A pe egbẹ́ náà láti wá seré ní ayẹyẹ tí gbajúgbajà olóṣèlú àti Agbẹjọ́rò Olóyè D. O. A. Oguntoye tí ó ń gbé ní ìlú Ìbàdàn sẹ agbátẹrù rẹ̀, ọ̀pọ̀ gbajúmọ̀ Ilè Yorùbá ló wà ní ìkàlẹ̀, I.K Dairo ṣàfihàn àrà orin jùjú ẹ̀ èyí tó mú kí o gbayì lọ́wọ́ àwọn gbajúmọ̀ tó wà ní ìkàlẹ̀, tí ọ̀pọ̀ nínu wọn pè é sí ayẹyẹ. Ní ìbẹ̀rẹ̀ 1960s, ó yí orúkọ ẹgbẹ́ rẹ̀ padà sí Blue Spot, Wọ́n sì jáwẹ́ olúborí nínu ìdíje orin jùjú ti amóhùnmáwòrán. Ní ìgbà náà, ó ṣe orúkọ àwo rẹ̀ nípa ìfowọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Haruna Ishola tí ó sí ṣàṣeyọrí pẹ̀lú òkìkí.Ní òpin 1950s, ìdìde I.K Dairo jẹ́ sábàbí pẹ̀lú ìgba òmìnira, A rí i gẹ́gẹ́ bí i olórin ìgbàlódé tó fún ìgbádùn àkókò náà ṣáájú òmìnira orílẹ̀-èdè. Àkókò náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àkókò ayẹyẹ ìjayé gbádùn fún àwọn olórin.

I.K Dairo ṣàṣeyọrí nínu orin kíkọ ní 1960s nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdí lára rẹ̀ ni: sísàmúlò orin ìbílẹ̀, ìgbé ayé òṣèlú 1950 tó fún un láyè láti ní àfojúsùn lórí Ìlù,Àlùjó, Rhythm, tó farahàn nínu orísirísi ẹ̀yà. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ ṣàmúlò oríṣiríṣi ọ̀nà orin láti oríṣiríṣi ẹ̀yà Yorùbá wọ́n tún ṣàmúlò Edo,Urhobo,Itsekiri àti èdè Hausa nínu orin wọn. Nítorí ètó àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ati lílo Yorùbá pẹ̀lú àṣà ijó Latin America àti sísàmúlò àwọn bàbá ìsàlẹ̀ jẹ́ àwọn ǹkan tó mú ìdàgbàsókè bá orin jùjú ní orílẹ̀-ẹ̀dẹ̀.Ó tún ló ọ̀nà orin méji nípa lílo ohùn orin Ìjèbú-jèsà púpọ̀ pẹ̀lú àlùjó àti àṣàyàn ọ̀rọ̀ onígbàgbọ́.

Ní ọdún 1962,Ó ṣe àgbéjáde orin ‘Salome’ ní abẹ́ Decca records.Orin náà jẹ́ àpapọ̀ èròjà ìbílẹ̀ ní Àṣà Yorùbá àti ìgbé-ayé ìlú gẹ́gẹ́ bíi àkòrí pàtàkì.Orin náà jẹ́ Òkan-gbòógì fún-un.Orin mìíràn rẹ̀ tí ó tún fẹ́ ju gbajú-gbajà náà nì ‘Ká ṣọ́ra’.

Nígbà mìíràn ni orin yìí máa ń jẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ìsotẹ́lẹ̀ ogun ìlú ní Nàíjíríà, tí ó sì ń ṣe ìkìlọ̀ nípa ìṣubú ìṣèjọba àìmógbọ́nwá.Ó sì tún ṣe àgbéjáde àwọn orin ìlúmọ̀ọ́ká tí ọ̀kan lára rè ń sọ nípa Olóyè Awolowo, ẹni tí ó wà ní àhámọ́ inú túbú ní àsìkò tí orin naa jáde.

Àwọn ẹgbẹ́ olórin yìí ṣe àmúlò fèèrè aláriwo ní èyí tí Ì.K fọn fèèrè náà.Àwọn ohun èlò orin tí ẹgbẹ́ yìí lò ni jìtá oníná,ìlù gángan,Agogo méjì,ìlù Àkúbà,ìlù Ògìdo,kílìpù,Soke,Agogo,ìlù sáḿbà.

Ìgòkè Dairo nínú ìran Olórin Nàíjíríà kò pẹ́ títí.Ní ọdún 1964, Olórin titun kàn,Ebenezer Obey,ti ń bò wá sí agbo wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́, nígbà tí yóò sì fi di òpin ọdún 1960,Obey àti King Sunny Adé ti di ìlúmọ̀ọ́ká Olórin ní ìgbà náà.

Síbẹ̀síbẹ̀,Dairo tún tẹ̀síwájú pẹ̀lú Orin ré àti ṣíṣe ìmọ̀múlọ ní Orílẹ́-èdè Europe àti North America ní odún 1970 àti 1980.Láàrin ọdún 1994 àti 1995,ó jẹ́ ọ̀kan lára ẹgbẹ́ Ethnomusicology ní Yunifásítì Washington,Seattle.Ó dágbére fún ayé ní Ọjọ́ keje, Oṣù Kejì, Odún 1996.Díẹ̀ lára àwọn àwo-orin tí ó ti kọ ní wọ̀nyí:

Ashiko, 1994, Xenophile Music
Definitive Dairo, Xenophile Music
I Remember, Music of the World
Juju Master, Original Music
Salome92
Ise Ori Ranmi Ni Mo Nse
I Remember My Darling,
Erora Feso Jaiye
Se B’Oluwa Lo Npese
Yoruba Solidarity
Mo ti yege
AshikoVols 1&2 Early 1970s’

 

General Prince Adekunle
Ọ̀gbẹ́ni General Prince Adekunle jẹ́ olórin juju ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọn bíi ní ọjọ́ kejìlélógún(22) oṣù kẹwàá ọdún 1942, ó sì kú ní ọdún 2017. Ó jẹ́ ọmọ Ẹ̀gbá, láti Abẹ́òkúta ní Ìpínlẹ̀ Ogun. Adekunle jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú olórin juju, pẹ̀lú ọ̀nà ọ̀tọ̀ kan pàtó nípa kíkọ orin juju. Gbajúmọ̀ olórin bíi Sir Shina Peters àti Segun Adewale bẹ̀rẹ̀ ìṣe orin kíkọ pẹ̀lú ọmọ ẹgbẹ́ wọn, àwọn the Western Brothers. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lọ kọrin ní ìlú England ní ọdún 1970 síwájú, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nìkan ni ó ti jẹ́ gbajúmọ̀(kì í ṣe kárí gbogbo orílẹ̀-èdè).

Ní ọdún 1930,Tunde King ni ó kọ́kọ́ dá orin juju sílẹ̀, tí Prince Adekunle tẹ́lẹ̀ Ìpìlẹ̀ náà. Ọ̀gbẹ́ni Fela Kuti àti àwọn mìíràn ni ó kọ́kọ́ fi ìpìlẹ̀ orin Afrobeat lé lẹ̀, èyí kópa gbòógì nínú orin Prince Adekunle àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ “The Western Brothers”. Ọ̀gbẹ́ni General Prince Adekunle jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ògbóǹtarìgì olórin juju.

Gbájúmọ́ oní juju àti oníjó soko, Dayo Kujore, jẹ́ olùkópa kan gbòógì nínú àwọn àwo orin Prince Adekunle tí ó sì máa ń ta Lead Guitar nínú àwọn orin rẹ̀ bíi “Aditu ede àti Eda n reti eleya”.

Ní oṣù karùn-ún ọdún 2004, Adekunle wà lára àwọn olórin tí ó jíròrò papọ̀ lórí àìṣe-ìtẹ́wọ́gbà orin juju, ní ìgbà tí ó ń takò èrò King Sunny Ade láti dá ẹgbẹ́ orin juju sílẹ̀. Prince General Adekunle kú ní ọjọ́ àbámẹ́ta, ọjọ́ kejì oṣù kẹsàn-án ọdún 2017.

Wasiu Alabi Odetola (“Oganla”, “Gauzu Fuji”, “Ijoba Fuji” )
A bí Wasiu Alabi Pasuma ní ọjọ́ kẹtadínlọ́gbọ̀n oṣù kọkànlá ọdún 1967. Ó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ẹdúnàbọ̀n-Ifẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ó lo kékeré àti ọdún díẹ̀ gẹ̀gẹ̀ bí ọ̀dọ̀ ní agbègbè Mushin ní ìpínlẹ̀ Èkó.

Ìya rẹ̀, ìyẹn Alhaja Adijat Kubura Odetola tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Ìyàwó Ànọ́bì nìkan ni ó tọ́ ọ dàgbà, tí ó sì máa ń gbé oríyìn fún nínú àwọn orin rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi igi-lẹ́yịn-ọgbà fún un.

Ọ̀dọ́mọdẹ́ Pasuma bẹ́rẹ́ sí kọ orin rẹ̀ fúnra rẹ̀ ní ọdún 1984 lẹ́yin tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ni wo K1 De Ultimate gẹ́gẹ́ bí àwòkọ́ṣe lẹ́yìn tí K1 gbé àwo orin rẹ̀ àkọ́kọ́ jáde tí ó pè ní Talazo 84 ní ọdún 1984. Àwo orin yìí tí ó gba oríyìn ńlá láti ọ̀dọ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ló ti Pasuma láti gbé àwo orin tiẹ̀ àkọ́kọ́ náà jáde ní ọdún 1993. Àwo orin tí ó pè ní Recognition ní ó gbé jáde ní ọdún 1993. Láti ìgbà náà, ó ti gbé àwo orin tó lé ní Ọgbọ̀n (30) jáde tí ó sì jẹ́ ọ̀kan lára olórin Fújì tó gbajúgbajà tó sì lààmì-laaka níbi iṣẹ́ orin náà ní orílẹ̀-ẹ̀dẹ̀ Nàìjíríà.

Ó tí bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olórin mìíràn kọ orin papọ̀ nínú èyí tí a ti rí Bọla Abímbólá àti King Sunny Ade. Yàtọ sí pé ó ń kọrin, ó tún máa ń kópa nínú àwọn fíìmù àgbéléwò ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nínú èyí tí a ti rí Ìyànjẹ àti Alénibáre.

Ní ọjọ́ kẹfà osù kẹjọ ọdún 2015, ó fi ẹ̀yìn àwọn bíi Olamide, Phyno àti Flavour bẹ́lẹ̀ láti kógo já gẹ́gẹ́ bíi Olórin Ilẹ̀ wa tó peregedé jù lọ ti ọdún náà (Best Indigenous Artist) níbi àmì-ẹ̀yẹ kan tí àjọ Nigeria Entertainment Award ṣe agbátẹrù rẹ̀.

Ní ọdún 2020, ó gbé àwo orin kan jáde tí ó pè ní MMM (MONEY MAKING MACHINE) Ó gbé àwo orin yìí jáde lásìkò àrùn bojú-bomú tó gba àgbáyé kan lọ́dún náà (COVID 19). Ó ṣàlàyé pé òun gbé àwo orin yìí jáde láti lè jẹ́ kí àwọn olólùfẹ́ òun lè máa fi gbádùn ara wọn nílé nígbà tí ìjọba ti fi òfin de àkójọpọ̀ àwọn ènìyàn púpọ̀ nítorí àrùn tó gba àgbáyé kan. Àwo orin MMM yìí wá jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú gbogbo àwọn àwo orin rẹ̀ torí bó ṣe kọ jálé-jáko pàápàá jù lọ láàrin àwọn tó ka orin fújì gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà orin àtijọ́.

Ó gba àmì-ẹ̀yẹ Best International Music Video ní ọdún 2021 eléyìí tí Hollywood àti àjọ African Prestigious Awards (HAPAwards) ṣe agbátẹrù rẹ̀.

Ní ọdún 2022, ó gbé àwo orin kan jáde tó pè ní Fuji Ìgbàlódé (Afro Fuji) pẹ̀lú Qdot, wọ́n pe àkọlé orin náà ní Ọmọ Ológo. Ó sì tún padà gbé àwo orin méjì mìíràn jáde tí ó pè ní: Legendary and December Tonic titled Human Nature.

Akorede Babatunde Okunola (Saheed Osupa or King Saheed Osupa K.S.O)
A bí Saheed Osupa ní agbègbè Mosafejo ní Ajegunle ní Ìpínlẹ̀ Èkó ní ọjọ́ keje oṣù kẹjọ ọdún 1969 ṣùgbọ́n ó dàgbà sí ìlú Ìbàdàn, olú-ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Bàbá rè, Moshood Ajiwere Layeye jẹ́ òǹkọrin wéré tí ó sì jẹ́ bí ẹ̀gbọ́n fún gbajúgbajà olórin Fújì Ayinde Barrister.

Saheed Osupa lọ sí ilé-ìwé Amuwo Odofin High School ní ìlú Èkó níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní ọdún 1987. Ní ọdún 1992, ó gba ìwé ẹ̀rí National Diploma ní ilé-ìwé gbogbonìṣe ti Ìlú Ìbàdàn níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ètò okòòwò ìyẹn Business Administration. Ó jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ jáde American International College níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Networking Operations.

Saheed Osupa bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ gẹ́gẹ́ bíi màjèsín ní ọdún 1983 gẹ́gẹ́ bíi òǹkọrin Fújì. Àkójọpọ̀ àwo orin rẹ̀ àkọ́kọ́ ló pè ní Fuji Fa Disco nígbà tí Fuji Blues tẹ̀lé e. Ó ti gbé àwo-orin tó ti lé ní Ogójì jáde nínú èyí tí àwo orin Mẹ́rin-lọ́kan (4 in 1) tí ó pè ní Mr Music wà pẹ̀lú. Ní ọdún 2008 Ayinde Barrister kéde Saheed Osupa gẹ́gẹ́ bíi Ọba orin Fuji (King of Fuji Music).

Saheed Osupa ni ẹni tó ṣe àgbékalẹ̀ orin Hip Fuji. Ní ọjọ́ kejìlá oṣù kẹfà ọdún 2018, ó ṣe àgbéjáde awo orin HIP FUJI àkọ́kọ́ tó pè ní: Non Stop. Ní ogúnjọ́ oṣù kejìlá ọdún 2014, Saheed Osupa gbé orin Hip-hop kan jáde tó pè ní “Vanakula” eléyìí tí K-Solo ṣe agbátẹrù rẹ̀. Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹ́rin ọdún 2015, ó gbé orin mìíràn tí K-Solo ṣe agbátẹrù rẹ̀ jáde tí ó pè ní “African Beauty” pẹ̀lu Yetunde Omobadan. Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹjọ ọdún 2015, ó kópa nínu orin Womi tí Seriki kọ.

Ní ọjọ́ keje oṣù kọkànlá ọdún 2015, orúkọ Saheed Osupa náà wà nínú orúkọ àwọn òǹkọrin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ti lààmì-laaka jù lọ tí àjọ The NET’s “Most successful Nigerian Musicians” gbé jáde.

Saheed Osupa ti kópa nínu fíìmù àgbéléwò Yorùbá tó lé ní Ọgbọ̀n. Ó sì ti gbé àwọn àwo orin wọ̀nyí jáde:

Fuji Fa Disco

Fuji Blues
Fuji Demonstration
Master Blaster
Stainless Fuji
Fuji Boggie
Unbeatable
Shuffle Solo
Ovation
Scores
Hot Shot
Advice
New Edition (Shuffle Solo 11)
Authentic
Big Daddy
Champion
London Delight under Marvin Giwa Promotion
African Delight
American Fuji Slide
World Tour
London Extra
Respect and Reliable – 2 in 1
Fuji Icon
Endorsement – 3 in 1
Mr. Music – 4 in 1
Marriage Affair
Barrybration
Euro Splash
Time Factor
Impact
Turn By Turn
The Main Man
Capability
Tested and Trusted – 2 in 1
Guaranteed
Lord of Music – 2 in 1
Transparency and Transformation – 2 in 1
New Dawn – 2 in 1
New resolution
Pacesetter 2017
Non Stop 2018
Dynamism (Monday 13 August 2018)
C Caution 2019
Integrity (07/08/2019)
Permutation (23 December 2019)
Special request-2 nd 1(05/07/2020)
Eni Olohun (2020)
Permutation(2020)
Special Request (2020)
What Next (2020)
Diary (2021)
Direction(2021)
Power of Music (2022)
Fuji Template (2022)
Phenomenon
Àwọn fíìmù àgbéléwò tí ó ti kópa nìwọ́nyí:

Eni Eleni
Ero Sese Koowe
Ese Mefa Laye
Ose Maami
Ashiru Ejire
Onibara Ogunjo
Iku Oba
Igba Iwase
Agbeere Oju
Alukoro
“Aroba(Fable)”
Osoro baba ojo
Oloju ede
Adigun olori odo
Onimoto
Olokiki Oru 1,2 & 3

Wàídì Àyìnlá Yusuf Gbogbolòwò tí a mọ̀ sí Àyìnlá Ọmọwúrà
Wàídì Àyìnlá Yusuf Gbogbolòwò tí a mọ̀ sí Àyìnlá Ọmọwúrà. Ọmọwúrà jẹ́ ọmọ Yusuff Gbogbolòwò, alágbẹ̀dẹ, ati Wuramotu Morẹ́niké, ní Loko, Abéòkúta. Wọ́n bí i ní ọdún 1933 ó sì kù ní ọjọ́ kẹfà osù karùn-ún ọdún 1980. Kò ní ẹ̀kọ́ ilé – ìwé ò bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ ní àgbẹ̀dẹ bàbá rẹ̀ sùgbọ́n ó fi sílẹ̀ ó sí lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ oríṣìíríṣìí gẹ́gẹ́ bíi awakọ̀, alápatà ,kápẹ́ńtà àti ọmọ ọkọ̀ akérò ṣùgbọ́n Adéwọlé Àlàó ṣe àwárí rẹ̀. Oniluola, ẹnití ó padè di olórí onílù rẹ ti o sí bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ni Olalomi,ti ẹ̀yà Àpàlà.

Ọmọwúrà ní àwọn olórin tí ó ń bá jà láì yọ àwọn aṣájú rẹ bíi Hárúnà Ìshòlá , tí ó padà wá gbà lásíwájú. Ó bá Àyìndé Barrister, Fatai Olowonyo, Yesufu Olátúnjí ati Dáúdà Èpo Àkàrà ja.

Àwọn àríyànjiyàn wọ̀nyí nípa lórí àwọ orin rẹ̀ jákè – jádò . Wọ́n kíyè sí i pé ó máa ń yára bínú, ó sì lọ́wọ́ nínú lílo igbó àti àríyànjiyàn.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọmọwúrà kò kàwé , ó ní ìmọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń lọ lọ́wọ́, ó sì ní ẹ̀ẹ̀bù fífi ọ̀rọ̀ ṣeré, òwe, ọ̀rọ̀ àsọyé àti àkàwé. Ó jẹ́ ẹni tí ó máa ń ṣàsọye àwùjọ àti alárìwísí bákan náà bíi olùkọ́ ìwà. Nígbà gbogbo ó ṣiṣẹ́ bí i agbẹnusọ fún sísọ àwọn ètò ìjọba sí àwọn ènìyàn àti pé ó tún jẹ́ òjíṣẹ àwọn ènìyàn padà sí ìjọba. Nínú awo orin 1976, Owo Udoji, o gboríyìn fún ìjọba fún àfikún owó oṣù ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí ó rí, ó bèèrè fún àfikún ní ẹ̀ka aládàáni. Nínú orin Owó Ilé Ẹ̀kọ́, Ó sàlàyé òfin yíyálò ìlú Èkó fún àwọn olùtẹ́tísí rẹ̀ ó sì gbóríyìn fún ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó tí Mobolaji Johnson darí fún ètò tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣe. Ó ní ipa lórí èsì àwọn ènìyàn si ètò ìmúlò náà o sí ṣàlàyé Ìkànìyàn Orílẹ-èdè ti 1973 nínú àwo-orin rẹ̀ “National Census” . Ní àfikún sí àwọn ọ̀ràn lọwọlọwọ, ó lo àwọn àwo-orin rẹ lati gbé pàtàkì àwọn iṣẹ́ eré ìdárayá ga. Orin rẹ̀ tún wàásù ìyípadà rere ní àwùjọ ó sì ṣe afihan ọ̀fọ̀ àti ayẹyẹ. Ó tún jẹ́ alárìwísí fún àwọn obìnrin tí o ń pa àwọ̀ wọn dà àti àwọn obìnrin panṣágà.

Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìnagijẹ ti ó sì gba moniker, nítorí wíwú rẹ̀ tí ó wuyi nínú àwọn agbádá tí a ṣe ẹ́lù léésì Swiss àti ohun ọ̀ṣọ́ góòlù. Àwọn ìnagijẹ rẹ̀ mìíràn pẹ̀lú Egúnmọ́gàjí, Anígilágé àti Àlùjànnú Eléré tí ó ṣe àfihàn ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí ó burújù ní orin ìgbà náà. Ọmọwúrà je Mùsùlùmí nípa ìbí, ó sì ń ṣe ẹ̀sìn náà. Ó ṣe Hajj ní 1975. Ó sì tún ṣe ìgbéyàwó ni ìlànà èsìn náà. Ó’ fẹ́ Áfúsátù ti àwọn ile Eleni àti Táwàkálítù Owonikoko. Ó ṣe àwọn ìgbàsílẹ̀ LP 22 èyítí ó jẹ àgbéjáde láti ọwọ́ EMI records ( tí ó ti di Ivory record), méjì nínú àwọn awo orin rẹ ní ó jáde lẹ́yìn tí ó kú tán tí ó sì tún sì wà lórí àtẹ orin.

1972 – National Population Census

1972 – Challenge Cup ’72

1973 – Orin Owo Ile Eko (Lagos Rent Edict)

1973 – Challenge Cup ’73

1974 – Challenge Cup ’74

1976 – Owo Udoji

Owo Tuntun

 

Ikú

Omowúrà ni wọ́n pa nínú ìjà ilé-ìṣèré kan ni Oṣù Karùn-ún ọjọ kẹfà, ọdún 1980, ní ọjọ́-orií mẹ́tà-dín-láàdọ́ta. Ó kú nítorí ìkọlù ọpọlọ lẹ́yìn tí Bayewu, alákóso rẹ ní àkókò yẹn, kọ́ ọ lórí pẹlu ìgò ọtí. Wọ́n mú Bayewu lọ sí kootu, a sì dá a lẹ́bi ikú lẹ́yìn ọdún diẹ. Ni ọjọ tí ó ku, EMI Records gba àkọsílẹ̀ pé o kere ju àádọ́ta ẹgbẹ̀rún ẹ̀dà tí wọn tà lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àwo orin rẹ̀.

Lẹ́yìn ikú Omowura ni 1980 àti Haruna Ishola ni 1983, ni òkìkí orin Àpàlà dínkù, a sì ti rọ́pò rẹ̀ pẹ̀lú orin Fuji.

Yusuf Olatunji (Baba Legba or Baba L’Egbaa)
Yusuf Olatunji ni a sọ pé a bí i ni ọdún 1905 tàbí 1906 ní abúlé kan tó ń jẹ́ Gbegbinlawo ní Ìpínlẹ̀ Ogun ní gúúsù-ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà, (bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìdáhùn kan ṣi wà nípa ibi tó ti bí i).

Ìyípadà rẹ sí ìsìlámù ní àárín ìgbésí ayé rẹ ràn án lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ orin Yorùbá. A bí i gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, ó sì ti wá láti Iseyin ní Ìpínlẹ̀ Ọyọ. A mọ̀ ọ́ ṣáájú gẹ́gẹ́ bí Joseph Olatunji. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ ní ọdún 1937 pẹ̀lú àkọ́kọ́ àkọsílẹ̀ rẹ, ó sì darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Abibu Oluwa ní ọdún 1927.

Ó kú ní ọjọ́ kẹtàlá, oṣù kejìlá, ọdún 1978, pẹ̀lú ọdún 74. Ó fi ọmọ mẹ́rin àti iyawo mẹ́ta sílẹ̀. Olatunji jẹ́ ọ̀rẹ́ ti aláìkú Lamidi Durowoju, Jimoh Isola tó kú, tó wà ní ìkànsí ní ipari ọdún mẹ́tàdínlógún, Raji Orire, Badejo Okunsanya àti àwọn ọkùnrin míì tó lágbára. Wọ́n ni àwọn ọlọ́rọ̀ tí ó máa ń kọ orin fún. Ó tún kọ orin ìyìn púpọ̀ fún àwọn ẹgbẹ́ awujọ tó lágbára nínú apá gúúsù-ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà.

Obinrin ọlọ́rọ̀ kan tó ń jẹ́ Alhaja Kuburatu Abike Adebisi, tó mọ̀ sí cash Madam ní Abeokuta, rán án lọ sí ilé ìwòsàn ní òkè òkun, ó kú ọdún méje lẹ́yìn náà.

Bola Are
A bí Bola Are ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹwàá ọdún 1954 ní ìlú Erio ni ìjọba-ìbílẹ̀ ìwọ̀-oòrùn Èkìtì ní ìpínlẹ̀ Èkìtì ní apá ìwọ̀-oòrùn gúúsù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sí inú ẹbí alàgbà Babayomi àti arábìnrin T.A Babayomi tí wọ́n wá láti Erio ní ìpínlẹ̀ Èkìtì ìyẹn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Wòlíì mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wò ó dàgbà ní ilé-ìjọ àpọsítélì ti Kírísítì ìyẹn Christ Apostolic Church , àwọn ni Ajíyìnrere Ayodele Babalola, Wòlíì Babajide, Wòlíì Akande àti Wòlíì T.O Obadare. Ó lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò rẹ̀ ní orí-òkè láti máa gba ìmísí lọ́dò Ẹ̀mí-mímọ́.

Bola Are bẹ̀rẹ̀ ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Christ Apostolic Church (CAC) primary school ní ìlú abínibí rẹ̀, ó sì tẹ̀ síwájú láti ka ìwé mẹ́wàá ni ilé-ìwé Christ Apostolic Church Grammar school ní Efon Alaaye ní ìpínlẹ̀ Èkìtì kí ó tó tẹ̀ síwájú sí ilé-ìwé gbogbonìṣe ti Ìlú Ìbàdàn níbi tí ó ti gba ìwé-ẹ̀rí gẹ́gẹ́ bíi Olùṣirò-owó. Ní oṣù keje ọdún 1985, ó gba àmì-ẹ̀yẹ ìfidánilọ́lá gẹ́gẹ́ bíi ọ̀mọ̀wé nínú ẹ̀kọ́ orin ní ilé-ìwé gíga St. Johns University.

Bola Are ṣe ìgbéyàwó ní ọdún 1977 pẹ̀lu Olóògbé Àlùfáà J.O Are tí Ọlọ́run sì fi Ọmọ jíǹkí wọn. Àwọn ọmọ wọn náà sì jẹ́ Akọrin àti Òǹkọrin.

Àjọ tó ń polongo ìyìnrere káríayé ti Bola Are ìyẹn Bola Are Gospel Foundation International ń gbìyànjú láti pèsè fún àwọn tí wọn kò rí ọwọ́ họrí ní orílè-èdè Nàìjíríà.

Eléyìí tí wọ́n gbé kalẹ̀ ní ọdún 1995. Ó ṣe àgbékalẹ̀ yàrá ìká-orin sílẹ̀, ilé-ẹ̀kọ́ fún orin ìyìnrere káríayé ní ọjọ́ keje oṣù keje ọdún 1990. Láti fún àwọn olórin ẹ̀mí ní ààyè tí yóò gbé wọn dé ọ̀dọ̀ Olúwa. Ilé-ẹ̀kọ́ náà wà ní CAC Àgbàlá Olúwa ní òpópó-ònà Bola Are Ogbere Ìdí-Obì, lẹ́gbẹ Airport Quaters ní Ìbàdàn báyìí. Bọla Are Òkìkí Jésù Records International. Bola Are ṣe ayẹyẹ ogójì ọdún lórí ìtàgé ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kẹwàá ọdún 2013.

Bola Are bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ kí ó tó pọmọ ọdún méjì. Àwọn òbí rẹ̀ sọ fún un pé ó bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ ní ó ku ọjọ́ díẹ̀ kó ṣe ọjọ́-ìbí rẹ̀ àkọ́kọ́. Eléyìí jẹ́ kí ó ka ara rẹ̀ kún ẹni tí a bí mọ́ orin. Bola Are bẹ̀rẹ̀ ẹgbẹ́ akọrin tó pè ní Bola and Her Spiritual Singers ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹfà ọdún 1973. Ní oṣù kẹjọ ọdún 1977, ó gbé awo orin rẹ̀ àkọ́kọ́ tó pè ní Bàbá Kú Iṣẹ́ jáde.

Títí di ọdún 2014 , àwo orin Bola Are tó ti jáde ti lé ní Àádọ́rin.

Divine Praise of the King Of Kings – 1965

Ajaga Babiloni Wooo– 1967
Anointed Praise 2– 1970
Bola Are Live– 1971
Agbara Esu Ko Da Nibiti Jesu Gbe Njoba– 1971
Homage 1– 1974
Halleluyah Jesus Lives– 1974
Adura Owuro– 1977
Baba Kuse– 1977
Anointed Praise 1– 1979
Jesus Is Coming Back, Be Ready!– 1981
Bibo Jesu Leekeji– 1988
Gbongbo Idile Jesse– 1991
Homage 2(Tribute To Apostle T.O Obadare) – 1995
Lion Of Judah– 1995
Oore Ofe– 1998
Power In Praise– 2000
Apostle Joseph Ayodele Babalola– 2000

Sulaimon Alao Adekunle (KS1 Malaika)
A bí Sulaiman Alao Adekunle ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù Kejì ọdún 1973. O bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin kíkọ ní ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀ ní ilé-kéú ní agbègbè kan tí à ń pé ní Agége ní Èkó níbi tí ó ti ń báwọn jí wéré (orin tí wọ́n fi ń jí àwọn mùsùlùmí lásìkò àwẹ̀ ní ìdájí) kí ó tó kó ẹgbẹ́ akọrin fújì jọ ní ọdún 1983. Pèlẹ́ àwọn ẹgbẹ́ akọrin rẹ̀ ìyẹn Tekoye Fújì Organisation, ó ṣeré ní orílẹ̀-ẹ̀dẹ̀ United States of America láti ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kọkànlá ọdún 1997 tí ó sì gbádùn ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe yí nǹkan bí ìpínlẹ̀ mẹ́ẹ̀dógún kiri níbẹ̀ kí ó tó padà sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pẹ̀lú ohun èlò orin tí owó rẹ̀ lé ní ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ́ náírà. Láti ìgbà náà ló tí mú iṣẹ́ yìí ní ọ̀kúnkúndùn tí ó sì ń gbé ẹ̀yà orin Fuji kárí ayé.

KS1 Malaika ti kọ orin àjọkọ pẹ̀lu onírúurú akọrin nínú oríṣìíríṣìí ẹ̀yà orin. Ó bá àwọn akọrin ẹ̀sìn mùsùlùmí ṣiṣẹ́ papọ̀ dáadáa nípa bí ó ṣe máa ń kópa nínú àwọn orin wọn. Àwọn orin rẹ̀ ló ti di gbajúgbajà láàrin àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ àti fújì ni oo pẹ̀lú Hip-hop.

Malaika ń kọ orin, ó ń ṣe àtòjọ orin bẹ́ẹ̀ náà ló ń gbé àwọn orin rẹ̀ jáde fúnra rẹ̀.

Ọlọ́run fi ohùn orin lórísìírísìí kẹ́ ẹ, àwọn orin rẹ̀ sì máa ń ṣe àmúlò ohun èlò orin ìbílẹ̀ tí ilẹ̀ adúláwọ̀ àti ilẹ̀ Nàìjíríà, àwọn ohun èlò bi: Gángan, Ìyá Ìlù, Bàtá, Ṣákárà, Agogo àti àwọn bíi Guitar, Hawaiian Guitar, Keyboard àti Saxophone. Pẹ̀lu Lílé àti Ègbè lọ́nà tó yàtọ tí gbogbo àwọn ènìyàn wá ń lò báyìí. Orin Malaika jẹ́ orin tó dùn létí tó sì ṣeé jó sí. Ìrìn-àjò káàkiri àgbáyé tí ó máa ń rìn ti sọ ọ́ di gbajúgbajà olórin nílẹ̀ yìí àti òkè òkun.

 

Abass Akande Obesere (Omo Rapala)
A bí Abass Akande Obesere ní ogúnjọ́ oṣù kìíní ọdún 1965, Òṣèré ni, akọrin ni, olóòtú àwo orin sì ni pẹ̀lú ní orílẹ̀-ẹ̀dẹ̀ Nàìjíríà tí ó sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn, ìlú tó tóbi jù ní agbègbè ìwọ̀-oòrùn Nàìjíríà. Gbajúgbajà olórin Fújì ní, Obesere yọ bọn̄bọ sí agboolé orin nípa àrà ọ̀tọ̀ tí ó gbà gbé orin rẹ̀ kalẹ̀ pẹ̀lú onírúurú àjásà tí ó máa ń jù sí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀. Ó tẹ̀lé ipa àwọn tó ti lààmì-laaka níbi iṣẹ́ orin bí Sikiru Ayinde Barrister. Obesere ti gbé àrà ọ̀tọ̀ fújì rẹ̀ yìí káàkiri àgbáyé. Ó tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn pẹ̀lu ilé-iṣẹ́ tó ń gbé orin jáde tẹ́lẹ̀ ìyẹn Sony Music kí ó tó kúrò níbẹ̀ lọ sí ibòmíràn torí ọ̀rọ̀ owó. Nínú iṣẹ́ orin rẹ̀, ó ní orogún iṣẹ́ pẹ̀lu K1 De Ultimate tí òun náà jẹ́ gbajúgbajà olórin.

O ti tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn pẹ̀lu ilé-iṣẹ́ Mayors Ville Entertainment tí wọ́n ń ṣe agbátẹrù fún àwọn òṣèré, ilé-iṣẹ́ tó jẹ́ ẹ̀ka kan lára ilé-iṣẹ́ Maxgolan Entertainment Group tó fi ìkàlẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Àwọn orin tí ó ti kọ.

“Introduction (1992)”
“Mr. Magic (1992)”
“Oodua”
“Diplomacy”
Elegance
“Live in Europe”
“Asakasa” (Sony)
“O.B.T.K” (Sony)
“Mr. Teacher” (Sony)
“Omorapala Overthrow” (Dudu Heritage)
“American Faaji Series 1&2” (Dudu Heritage)
Mr Teacher
“His Excellency” (Bayowa)
“Egungun Be Careful (Bayowa)
“Old Skool Lape” (Bayowa)
“Apple Juice” (Bayowa)
“Okokoriko” (Bayowa)
“Obaadan” (Bayowa)
“Effissy” (Corporate Pictures)
“Confirmation” (Corporate Pictures)
New Face
Jaforie
Alaimore (Ingrate)
Egungun Be Careful
Baby Mi sexy
Murderer
EKO
Paraga
Ebelesua
Mobinu tan
Emi ni
Basira
Slow Slow
Ja Fo rie
Ibi ni ma kusi
Ki nan so
Obesere tilo
Alhaji (ft Seriki)
Ki nan so
Baby mi (Ft 2star)
Wind E
E ma le won
GBO se yen so
Asakasa
O.B.T.K
Mr Teacher
Ileke Idi
Omo iku
Mr Teacher part II
Baba Baba Tide
Amin ase
Ibaje

Adewale Ayuba (Mr. Johnson)
Ayuba wá sí ayé ni ọjọ́ kẹfà oṣù Kàrún un ọdún 1966 ni ilu ikene Remo ogún Nàìjíríà. Ó dàgbà gege bí ómode Olórin tí ó sì ti bere si ni kò orin labele láti ọmọ ọdún mejo. Èyí gan lọ mú ú tó mọ ìṣe orin leyin ilé ìwé gírámà rẹ ni ile eko Rẹmo ni sagamu ipinle ogun

Bí ó ti lè jẹ pe o wole láti kó nípa ìṣe ona rẹ ni ile eko giga gbogbo nise tí ìjọba ipinle Abeokuta, ṣùgbọ́n ìṣe orin kiko rẹ lọ dúró sí àárín gbùngbùn. Ayuba gbé àwo orin rẹ àkókò tí ó pè ní ibère (beginning) jáde ní ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ní ìbèrẹ̀ ọdún 1990, pelu èyí ó tètè dìde gidi gidi nínú àwọn tí wón kó orin fuji. Ayuba fọwọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú Sony Music (Nàìjíríà) láti ṣe àkọ́kọ́ àwo-orin , Bubble, tó jẹ́ pé ó gbé jáde ní ọdún 1991, tó sì mú Ayuba wá sí ìmọ̀lára àgbáyé. Bubble jẹ́ àkókò nínú ìtàn tí àwo-orin fújì tó gba àmì ẹ̀yẹ tó gbòòrò, tó sì gbé orúkọ rẹ sókè lórí àwọn ìgbéléwọ̀n orin fún oṣù mẹ́fa pẹ̀lú, àti pé ó gba ọ̀pọ̀ ẹ̀yẹ ní Nigerian Music Awards (NMA). Ó tún gba àmì-ẹ̀yẹ olórin ọdún, pẹ̀lú ẹ̀yẹ àwo-orin ọdún, ẹ̀yẹ orin ọdún, àti ẹ̀yẹ Fuji to dára jùlọ ọdún mẹ́rin pátápátá. Pẹ̀lú aṣeyọrí Bubble, Ayuba dé ipò gíga nínú iṣẹ́ rẹ ní Nàìjíríà.

Iṣẹ́ ọpọlọpọ tó ní imọ̀ ẹrọ gíga àti ohùn tó yàtọ̀ rẹ yí ìwòye Fuji padà. Fun àkọ́kọ́ nínú ìtàn, àwọn olóyè Nàìjíríà, tí wọ́n ti kọ Fuji sílẹ̀ títí di àsìkò yẹn, bẹ̀rẹ̀ sí í gbà á. Léyìn aṣeyọrí Bubble, Ayuba gbé àwo-orin míràn, Mr. Johnson Play For Me (pẹ̀lú Sony Music Nigeria), tó tún di aṣeyọrí lẹ́sẹ̀kẹsẹ ní ọdún 1992. Ní ọdún 1993, Ayuba fọwọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú Premier Music (Nàìjíríà) kí ó tó bẹ̀rẹ̀ irin-ajo rẹ àkọ́kọ́ ní etíkun West Africa, tí ó ṣe àfihàn ní orílẹ̀-èdè mẹ́ta nínú Afirika.

 

Ayuba ti gbé  àwọn àwo-orin wón yìí jáde:

Ibere (Beginning) 1986
Igida (Tribute to Obafemi Awolowo) 1987
Bonsue Knockout Ife Love 1988
Olorun ni gbe niga 1989
‘Bonsue Gold 1990
Bubble 1991
Mr Johnson Play For Me 1992
Buggle D (Dance) 1994
Move Up 1995
Fuji Music 1995
Fuji Time 1996
Fuji Dub 1997
Back Head Bound (BHB) 1998
Acceleration 1999
Turn Me On 2001
Formula 2003
Gun Shot 2003
Fuji Satisfaction 2005
Ijo Fuji 2007
Mellow 2009
Ariya 2011
Sugar 2013
Happy People Remix 2015