Àwọn Òǹkọ̀wé Yorùbá

Kọ́lá Akínlàdé

Ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kẹfà, ọdún 1924 ni wọ́n bí Kọ́lá Akínlàdé ní ìlú Ayétòrò ní ìpínlẹ̀ Ògùn. Orúkọ àwọn òbí rẹ̀ ni Michael Akínlàdé àti Elizabeth Akínlàdé. Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni iṣẹ́ tí Michael Akínládé ń ṣe. Láàrín 1933 sí 1938, Kọ́lá Akínlàdé lọ sí Ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ St. Paul, Ayétòrò.
Ó ṣiṣẹ́ oko láti ọdún 1939 sí 1945 nítorí kò rí owó láti tẹ̀ síwájú nídìí ẹ̀kọ́. Nígbà tó ó di ọdún 1945, ó pa iṣẹ́ oko tì láti lọ di akọlẹ́tà fún gbogbogbòo. Nígbà tí ó dé ìlú Ìlaròó, iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọlẹ́tà fún gbogbogbòo sọ ọ́ di ẹni tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá, àwọn ọ̀daràn, àwọn afunrasí, àwọn agbẹjọ́rò, àti ilé-ẹ̀jọ́. Bákan náà, ó dá ilé-iṣẹ́ atẹ̀wétà sílẹ̀.

Ní ọdún 1951, ó fẹ́ ìyàwó rẹ̀ Àgbékẹ́ Akínlàdé. Ìlaròó ni ó ṣì wà nígbà ó kọ́ ara rẹ̀ ṣe ìdánwò G.C.E. tí University of London gbékalẹ̀. Latí ara àṣeyọrí rẹ̀ nínú àwọn ìdánwò rẹ̀, wọ́n pè é láti wá kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ òfin ní ìlú London ní ọdún 1952. Akínlàdé kò le è lọ sí ìlu London láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ nítorí àìlówó. Látàrí àìlèlọ sí London, Akínlàdé dá ìwé-ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ “Ẹ̀gbádò Progressive Newspaper” sílẹ̀. Láàárín ọdún 1966 sí 1969, ó kẹ́kọ̀ọ́ ní Obafemi Awolowo University.

Ọdún 1971 ni Akínlàdé bẹ̀rẹ̀ sí ní tẹ àwọn ìtàn-àròsọ ọlọ́rọ̀ geere ọ̀tẹlẹ̀múyé rẹ̀ jade. Ìwé ìtàn-àròsọ ọlọ́rọ̀ geere rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Ogun Ìdàhọ̀mì àti àwọn ará ìlú Ọbọgíran gba ipò kẹ́ta nínú ìdíje “Nigerian Festival of the Arts.” Kọ́lá Akínlàdé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé mìíràn tí ó kọ. Bí i Ìjọba Káúnsùlù (1959), Ìtàn Sọlómónì Ọba Ṣúlámítè Arẹwà Obìnrin (1959) Òwe Pẹ̀lú Ìtumọ̀ (1987), Ajá tó ń lépa ẸkùnOwó Ẹ̀jẹ̀ (1986), Ṣàǹgbá fọ́ (1986), Àṣírí Amòòkùnjalè Tú (2000), Ọmọ́gbèjà (2004). mọ́gbèjà nìkan ni ìwé eré-onítàn tí Kọ́lá Akínlàdé kọ́. Ìwé Òwe Pẹ̀lú Ìtumọ̀ tí Akínlàdé kọ jẹ́ àkójọpọ̀ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta òwe Yorùbá.

Akínlàdé jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwọn òǹkọ̀wé ìtàn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Yorùbá.

Joseph Fọlọ́runsọ́ Ọdúnjọ

A bí J.F. Ọdúnjọ ní ọdún 1904 ní ìlú Abẹ́òkúta. Ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ St. Augustine, Ìtésí, Abẹ́ọ̀kúta ni ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ọdún 1914. Ó lọ kọ́ iṣẹ́ olùkọ́ni ní Catholic Teachers Training College, Ibadan ní ọdún 1920. Lẹ́yìn tí ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyé ní ọdún 1924, ó di ọ̀gá ilé-ìwé ní St. Augustine títí di ọdún 1939. Nígbà tí ó kúrò níbẹ̀, ó lọ di ọ̀gá ilé-ìwé ilé-ìwé St. Paul ní Ebute-Metta láti ọdún 1940 sí 1946. Láàárín ọdún 1948 sí 1952, ó ṣe iṣẹ́ káàkiri àwọn ilé-ìwé ní agbègbè Èkó àti Abẹ́òkúta.

Ó ṣe iṣẹ́ lábẹ Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ gẹ́gẹ́ bí mínísítà fún ilẹ̀ àti iṣẹ́ títí di ọdún 1956. Bákan náà, láàárín ọdún 1963 sí 1976, ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ àti ọ̀gá àìmọye ẹgbẹ́. Òun ni olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ àwọn Olùkọ́ni ti Ìjọ Kátólíkì ní agbègbè Èkó àti Yorùbá (Federal Association of Catholic Teachers, Lagos and Yorùbá Province) ní ọdún 1936. Òun sì ni ààrẹ ẹgbẹ́ náà títí di ọdún 1951.

Ọdúnjọ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òǹkọwé tí ó gbé lítírésọ̀ Yorùbá alákọsílẹ̀ òde-òní lárugẹ, ó jẹ́ akéwì, ó sì kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé. Bí i Aláwíyé (ìwé kìíní dé karùn-ún), Àkójọpọ̀ Ewì Aládùn (1961), Agbàlọ́wọ́méri Baálẹ̀ JòǹtoloỌmọ Òkú Ọ̀run. Ibadan (1964), Kúyẹ̀ (1964), Kádàrá àti Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ (1967), àti Aláwíyé fún Àwọn Ọmọdé àti Àwọn Àgbà tí ó ń kọ́ Ìwé Yorùbá Ní Kíkà (1975). Àwọn ìwe Ọdúnjọ gbajúmọ̀ jù ni àwọn ìwé Aláwíyé àti Àkójọpọ̀ Ewì Aládùn.

Ọládẹ̀jọ Samuel Òkédìjí

Ìdílé Àpáàrà ní ìlú Ọ̀yọ́ ni wọ́n ti bí Ọládẹ̀jọ́ Òkédìjí ní ọdún 1929. Ọdún 1935 ni Òkédìjí bẹ̀rẹ̀ ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Methodist. Ilé-ìwé St. Andrew’s College Demonstration ni ó ti parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ọdún 1943. Òkédìjí ṣe iṣẹ́ olùkọ́ ní ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Fìdítì ní 1944 kí ó tó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ó lọ kọ́ iṣẹ́ olùkọ́ni ní Wesley College ní Ìbàdàn. Ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ọdún 1948 pẹ̀lú ìwé ẹ̀rí Grade II.

Nígbà tí ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó tún tẹ̀síwájú láti ṣe olùkọ́ni ní àwọn ìlú bí i Ògéré-Rẹ́mọ, Ìpẹru, Ìtàpá-Èkìtì, Ọ̀wọ̀, Ijù, Ìta-Ògbólú, Mushin àti ní ìlú Èkó. Lẹ́yìn tí ó ti ṣe olùkọ́ni fún ọdún díẹ̀, o fi iṣẹ́ ìjọba sílẹ̀ láti lọ́ kẹ̀kọ̀ọ́ gboyè nínú iṣẹ́ olùkọ́ni (Associateship Certificate of Education) ní ọdún 1975.

Ní ọdún 1966 ni Òkédìjí ti da ilé-ìtàwé sílẹ̀ ní ìlú Ilé-Ifẹ̀ lẹ́yìn tí ó kọ́kọ́ fi iṣẹ́ ìjọba sílẹ̀. Ó ta ìwé, òun fúnra rẹ̀ sì jẹ́ òǹkọ̀wé. Àwọn ìwé tí ó ti kọ ni Àjà lo Lẹrù (1969), Àgàlagbà Akàn (1971), Ọ̀gá ni Bùkọ́lá (1972), Rẹ́rẹ́ Rún (1973), Ìmúra Ìdánwò Yorùbá (1979), Atótó Arére (1981), Ṣàngó (1987), Bínú ti rí (1989), Ọ̀pá Àgbélékà (1989), Aájò Ajé (1997), Ìròyìn Ayò (1997), Ká rìn ká pọ̀ (2007), àti Àárọ̀ Ọlọ́mọge (2014).

Ọ̀kan gbòógì lára àwọn òǹkọ̀wé Yorùbá ni Ọládẹ̀jọ Òkédìjí jẹ́. Ó sì gbajúmọ̀ pupọ̀ fún ilò òwe rẹ̀ àti àwọn ìwé ìtàn-àròsọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀tà kí ó dálérí ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lápàdé àti amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tàfá. Bákan náà, ni àwọn ìwé eré-onítàn rẹ̀ méji Rẹ́rẹ́ Rún àti Ṣàngó ṣe gbajúmọ̀.

Solomon Adébóyè Babalọlá

Wọ́n bí Adébóyè Babalọlá ní ìlú Ìpétumodù ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kéjìlá ọdún 1929. Ó kàwé gboyè ní ilé-ìwé Acimota College ní Ghana ní ọdún 1946. Lẹ́yìn tí ó gboyè àkọ́kọ́, ó ṣe iṣẹ́ olúkọni ní Ilé-ìwé Igbobi. Ní ọdún 1948 ó gba owó ìránwọ́ kejí láti ka ìwé ní ilé-ìwé Queen’s College, Cambridge, ó sì gba oyè rẹ̀ ní ọdún 1952. Nígbà tí ó gba oyè rẹ̀ ní Queen’s College, ó padà sí ìdí iṣẹ́ olúkọni ní Ilé-ìwé Igbobi. University of London ni ó ti gba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ (Ph.D.).

Lẹ́yìn tí ó gba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tán, ó ṣe iṣẹ́ olúkọni ní Institute of African Studies, University of Ife àti gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú àwọn èdè àti lítírésọ̀ Adúláwọ̀ ní University of Lagos.

Ó jẹ́ akéwì àti onímọ̀ tí ó gbajúmọ̀ fún àwọn iṣẹ́ ìwádìí tí ó ṣe àti àwọn ìwé tí ó kọ lórí ìjálá, àlọ́, àti oríkì Yorùbá. Lára àwọn ìwé tí ó kọ ni ìjálá Àtẹnudẹ́nu (1956), Contents and Forms of Yorùbá Ìjálá, (1966), Àwọn Oríkì Orílẹ̀ (1967), Yorùbá Poetic Language: A Transition from Oral to Written Forms (1973), Orin Ọdẹ Fún Àṣeyẹ (1973), Àkójọpọ̀ Àlọ́ Ìjàpá. Apá kìíní (1982), Àkójọpọ̀ Àlọ́ Ìjàpá. Apá kejì (1985), Ewé Òmísínmisìn (1989), àti Àwọn Oríkì Orílẹ̀ Mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (2000).

Àrínpé Gbékẹolú Adéjùmọ̀

Ọjọ́ kẹrin, oṣù kẹ́ta ọdún 1964 ní ìlú Módákẹ́kẹ́. Ó lọ sí ilé-ìwé Obafemi Awolowo University ní ọdun 1981 sí 1995 ó sì gba àwọn oyè imọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú èdè àti lítírésọ̀ Yorùbá. Láàárín ọdún 1988 sí 2003, ó ṣe iṣẹ́ olùkọ́ni ní University Adó-Èkìtì. Ọdún 2003 ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ olùkọ́ni ní University of Ibadan. Ó ti ìdí iṣẹ́ yìí di Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú àwọn èdè àti lítírésọ̀ Yorùbá.

Lára àwọn ìwé tí Àrínpé Adéjùmọ̀ ti kọ ni Ẹyin Àparò (1998), Ròóre (2002),” Taa Lọ̀dàlẹ̀” (2001), àti “Ìtanijẹ” (2001). Adéjùmọ̀ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn òǹkọ̀wébìnrin Yorùbá òde-òní.